Oba of Benin




Ọba ti Benin jẹ́ alákòóso ìbílẹ̀ àti olùṣọ́ àṣà àwọn ẹ̀yà Ẹdó àti gbogbo àwọn ènìyàn tó ń sọ èdè tí ó rọ̀ mọ́ Ẹdó (Edoid). Ìjọba Benin ìgbà náà (kí á má ṣe dà á pọ̀ mọ́ orílẹ̀-èdè Benin ti òde-òní, tí a mọ̀ sí Dahomey tẹ́lẹ̀)[1] jẹ́ èyí tí àwọn Ẹdó (tí a tún mọ̀ sí ẹ̀yà Benin) pọ̀ jùlọ nínú rẹ̀. Ìran ọba yìí ni a ń pè ní "Ìtẹ̀ Ọba" (Oba dynasty), tí a sọ orúkọ rẹ̀ tẹ̀lé Ọba àkọ́kọ́ nínú ìran náà, Ẹwẹ́ká Kìíní,[2] ní nǹkan bí ọ̀rúndún kejìlá. Ìjọba Ogiso ni ó kọ́kọ́ wà ṣáájú ìtẹ̀ Ọba yìí.
Ní ọdún 1897, àwọn ọmọ-ogun Gẹ̀ẹ́sì tí iye wọn tó 1,200 lábẹ́ àṣẹ Sir Harry Rawson gbé ogun wá sí Benin (Benin punitive Expedition).[3] Ogun yìí wáyé gẹ́gẹ́ bí ẹ̀san fún dídá tí wọ́n dá àwọn Gẹ̀ẹ́sì lọnà ní abúlé Ugbine nítòsí Gwato ní ọjọ́ kẹrin Oṣù Kìíní ọdún 1897, láti ọwọ́ àwọn sójà Benin kan tí kò gba àṣẹ lọ́wọ́ Ọba; ìṣẹ̀lẹ̀ yìí yọrí sí ikú gbogbo àwọn Gẹ̀ẹ́sì tí wọ́n lọ yàtọ̀ sí ènìyàn méjì. Àwọn sójà Gẹ̀ẹ́sì náà ṣẹ́gun olú-ìlú Ìjọba Benin, wọ́n ba ìlú náà jẹ́, wọ́n dáná sun ún, wọ́n sì lé Ọba Benin, Ovonramwen, lọ sí ìgbèkùn fún oṣù mẹ́fà.[4] Àwọn ológun tí wọ́n lọ fún ẹ̀san yìí pẹ̀lú àwọn sójà ilẹ̀ Nàìjíríà àti àwọn ọ̀gá ogun Gẹ̀ẹ́sì tó wà ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà lásìkò ìmúnisìn. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ ọnà (tí a mọ̀ lápapọ̀ sí Ère Idẹ Benin) ni wọ́n jí gbé láti inú ààfin tí wọ́n sì tà wọ́n láti fi gba owó tí wọ́n ná sínú ogun náà padà.[5][6] Ovonramwen kú ní ọdún 1914,[7] kò sì padà gorí ìtẹ́ rẹ̀ mọ́.[8] Ọmọ rẹ̀, ọmọ-ọmọ rẹ̀, àti báyìí ọmọ-ọmọ-ọmọ rẹ̀ ti tọ́jú oyè àti ipò wọn gẹ́gẹ́ bí alákòóso ìbílẹ̀ ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ti òde-òní.[9]
Àtòjọ àwọn Ọba ti Ìjọba Benin
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Àkókò Ṣáájú Ìjọba Ilẹ̀-Ọba Ńlá (Pre-Imperial Benin, 1180–1440)
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
- Eweka I (1200–1235)
- Uwakhuahen (1235–1243)
- Ehenmihen (1243–1255)
- Ewedo (1255–1280)
- Oguola (1280–1295)
- Edoni (1295–1299)
- Udagbedo (1299–1334)
- Ohen (1334–1370)
- Egbeka (1370–1400)
- Orobiru (1400–1430)
- Uwaifiokun (1430–1440)
Ìtọ́kasí rẹ̀ wá láti:[10]
Àkókò Ìjọba Ilẹ̀-Ọba Ńlá (Imperial Benin, 1440–1897)
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
Àìdánilójú díẹ̀ wà nínú déètì àwọn ọdún tí àwọn ọba jagunjagun ti ìṣáájú jẹ.[11]
- Ewuare Ńlá (1440–1473)
- Ezoti (Ó jẹ fún ọjọ́ mẹ́rìnlá)
- Olua (1473–1480)
- Ozolua (1483–1504)
- Esigie (1504–1550)
- Orhogbua (1550–1578)
- Ehengbuda (1578–1606)
- Ohuan (1606–1641)
- Ohenzae (1641–1661)
- Akenzae (1661–1669)
- Akengboi ( 1669–1675)
- Ahenkpaye (1675–1684)
- Akengbedo (1684–1689)
- Oroghene (1689–1700)
- Ewuakpe (1700–1712)
- Ozuere (1712–1713)
- Akenzua I (1713–1735)
- Eresoyen (1735–1750)
- Akengbuda (1750–1804)
- Obanosa (1804–1816)
- Ogbebo (1816–1816) (Ó jẹ fún oṣù mẹ́jọ)
- Osemwende (1816–1848)
- Adolo (1848–1888)
- Ovonramwen N'Ogbaise (1888–1914)
Àkókò Lẹ́yìn Ìjọba Ilẹ̀-Ọba Ńlá (Post-Imperial Benin)
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- Eweka II (1914–1933)
- Akenzua II (1933–1978)
- Erediauwa (1979–2016)
- Ewuare II (2016–doni)
Ẹ tún wo
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Àwọn ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ "The Benin Kingdom | Pre-Colonial Political Systems". Nigerian Scholars (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2023-01-25.
- ↑ Ekeh, Peter Palmer; Society, Urhobo Historical (2007) (in en). History of the Urhobo People of Niger Delta. Urhobo Historical Society. ISBN 978-978-077-288-8. https://books.google.com/books?id=fFdeYB1lIPwC&dq=ogiso+ekeh+eweka&pg=PA3.
- ↑ ""Massacres committed in Africa during colonial times"". World Council of Churches (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2023-01-27.
- ↑ "Museum Insights / The Raid on Benin, 1897". africa.si.edu. Archived from the original on 2024-05-22. Retrieved 2022-06-25.
- ↑ "The kingdom of Benin was obliterated by the British, who still have the evidence on display". www.abc.net.au (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2020-11-29. Retrieved 2021-07-09.
- ↑ "Benin Bronzes: Germany to return looted artifacts to Nigeria" (in en-GB). BBC News. 2021-04-30. https://www.bbc.com/news/world-africa-56949003.
- ↑ "The British Conquest of Benin and the Oba's Return | The Art Institute of Chicago". archive.artic.edu. Retrieved 2023-01-27.
- ↑ "Ovonramwen | king of Benin | Britannica". www.britannica.com (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2023-01-25.
- ↑ "Leopard's Head Ornament". The Hunt Museum (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2025-11-11.
- ↑ Ben-Amos, Paula Girshick (1995). The Art of Benin Revised Edition. British Museum Press. p. 20. ISBN 0-7141-2520-2.
- ↑ Ben-Amos (1995). The Art of Benin Revised Edition. p. 32.
Àwọn ìjápọ̀ ìta
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]| Wikimedia Commons ní àwọn amóunmáwòrán bíbátan mọ́: Oba of Benin |
- Africa Reparations Movement | Ìpolongo fún dídá àwọn Ère Idẹ Benin padà
- Stories of royalty in brass. Collections Multimedia Public Access System, The British Museum, 2000.
- "The Obas that ruled Benin after the Ogiso dynasty" Archived 2023-12-07 at the Wayback Machine.. Edofolks–Àtòjọ àwọn Ọba ti Benin
- Benin kingdom Obas 1200AD–Date (pẹ̀lú àwọn fọ́tò) {látọwọ́ Edoworld}
- Benin Monarchial system {látọwọ́ Edoworld}
- Benin Traditional Temple and Cultural Center to the world
- Royal Art of Benin: The Perls Collection,